Sting Logo
All stories

Ah! Ìkùnlè Abiyamo o! MEE/MTE Fa Aso Èye Ya Mó EEE/BME Lára Níròlé Ojó Etì

Ezekiel Fasanya

13 December 20241 min read

By: Ezekiel Fasanya

Kàyéfì nlá lô jé fún àwon egbé agbábóòlu EEE/BME àti àwon olólùfé won lórí pápá ìseré níròlé òní nígbàtí góòlù láti òdò àwon alátakò won tíí se MEE/MTE bérè síní kolu ira won ni ojú ilé won, tí wón sí nà wón ní méjo sí òdo.


Sáájú ìfesèwonsè wón lóní, egbé agbábóòlu méjèèjí ti se dáradára tí wón sí tí jáwé olúborí ni àìmoye ìgbà. Sùgbón lóní tí wón kojú ira won tí wón sí fi igagbága, ògá ti fi ara hàn kedere.

Ìfesèwonsè náà jé èyí tí ó lágbára lópòlopò nítorí àwon egbé agbábóòlu méjèèjí múra wá láti jáwé olúborí. Níse ni wón kó ìpà bo ira won bí ení gba ìyàwó ara won.

Ègé orísirísi àti sóòtì ni wón fi dá ara won lólá. Àwon egbé agbábóòlu MEE/MTE fa ako yo gidigidi tí wón sí se dáradára. Àmó, níse ní àwon agbábóòlu EEE/BME bèrè síní gbá bóòlù sínú igbó bíi eni wípé ilè tí sú tí won kò sì ríran.

Oríire nlá gba lójé fún àwon egbé agbábóòlu bí wón se se àseyege nínú ìdíje náà to wáyé lóní. Alágbára EEE/BME tí subú! Tani yóó gbé won dìde?

Enjoyed this story?

Tap to show the newsroom some love — you can clap as much as you like.

Responses (0)

Be kind. Responses are public and anonymous.

No responses yet — be the first to weigh in.