Sting Logo
All stories

Ayé Mà Níkà O! CHE/PEE Sán Bànté ìyà Fun EEE/BME Níròlé Ojó Ìségun

Ezekiel Fasanya

10 December 20241 min read

By: Ezekiel Fasanya

Ohun ìyàlénu nlá lójé fún gbogbo àwon olùwòran lóní nígbàtí àwon agbábóòlu CHE/PEE so àwon alátakò wón tíí se EEE/BME di dìdìnrìn lórí pápá ìseré, ti wón sí nà wón ní mérin sí òdo.

Sáájú ìfesèwonsè wón lóní, egbé agbábóòlu méjèèjí ti se dáradára tí wón sí tí jáwé olúborí ni àìmoye ìgbà. Sùgbón lóní tí wón kojú ira won tí wón sí fi igagbága, ògá ti fi ara hàn kedere.

Ìfesèwonsè náà bèrè loni pelu akitiyan nlá láti òdò àwon egbé agbábóòlu méjèèjí ti wón sí n lépa lati so góòlù sínú àwòn. Kódà, ènìyàn le ti rò wípé awón egbé agbábóòlu EEE/BME ni yóó jáwé olúborí torí níse ni wón n sáré káàkiri lórí pápá pélú gbogbo agbára.

Sùgbón, iya nlá ni wón jé lówó àwon alátakò won. Níse ni àwon agbábóòlu CHE/PEE fi owó olá gbá won lójú, tí wón sí se wón básubasu. Góòlù méjì tó lágbára ni Màlíkì so sínú àwòn, ti Sinto átì Àjàgbé sí so góòlù eyokòòkan sínú àwòn pelu.

Gbogbo akitiyan àwon agbábóòlu EEE/BME láti dá góòlù díè padà ló já sí pàbó. Wón gbìyànjú gidigidi, sùgbón agbára wón ò tó.

Sí àwon agbábóòlu CHE/PEE, ekú oríire o!

Enjoyed this story?

Tap to show the newsroom some love — you can clap as much as you like.

Responses (0)

Be kind. Responses are public and anonymous.

No responses yet — be the first to weigh in.